ITAN ILU ILORINAPAKINNIđź‘Źđź‘Ź

EKU DEDE ASIKOYI EYAN ENIYAN MI DADA NI MO BAYIN EMI NI MA MO WA BAKANAA EYIN NI MA MO BA A KO NI BA WON LO IRINAJO ALODE NI ASE ELEDUMARE

ITAN ILU ILORINAPAKINNI👏👏
OPOLOPO ENIYAN LE MA RO PE SE MO JE OMO ILU ILORIN NI ATIPE TANI EMI NI OTITO MI O JE NKANKAN JU ERU OLĂ“HUN LO TIO DAMI ATIPE GBOGBO ILU TI O BA TI NI NKAN SE PELU OODUA OMO ILU IBE NI NI AKOKO GBOGBO ITAN TI MO BA SO O YATO SI AROSO TABI IRO NITORIPE BEENI NI TI ODODO, KEHE-KEHE  MAA N MU NI I PURO NI, ONA-OFUN KO NI GBOGBO, KO SOHUN TODUN N SO LAYE YII BII OOTO ORO, BI A BA TI BERE RE GEERE NI YIO MAA LO, AFI TEEYAN BA FEE PURO NIKAN NI YIO MA LO TIKOTIKO  BEE, OMO KAN KO LE GO TITI KO MA MO ILE BABA RE, OMO TA A BA BI TI KO BA MO ITAN ISEDALE BABA RE, OMO OLOMO NI.

 TOLOHUNLASE OMO OODUA BABA OWE ATI AKANLO EDE YORUBA KI OLĂ“HUN MA JE KIUN SISO AMIN OO

BEEYAN BA FEE SO ITAN YII, TO BA TI KO KINNI NAA LATIILE ARIYANJIYAN KAN KONI SI NIBE,YEKEYEKE NI YOO YE GBOGBO ENI TO BA N GBOO.BI ENIYAN BA FEE SO ITAN ILU NLA YII, BO BA BERE LODUN 1796,NIGBA TI AFONJA DITE MO ALAAFIN AOLE,OLUWARE YOO KAN MAA KO KEKE SAAJU ESIN NI, IYEN LOFA A TAWON KAN FI N SO PE NIGBATI WAHALA BA AFONJA NI OYOO LO SARE WA SI ILORIN, TO WAA FARA PAMO SIBE.

 KO SOHUN TO JOO, ELEYII KIISE ODODI.TABI TEEYAN BA FEE SO ITAN ILORIN, TO BA MU UN LATODUN 1813, NIGBATI ALFA FULANI TI WON N PE NI ALIM-AL-SAALIH KOKO DA ESE WO ILU ILORIN, OLUWARE YOO GBE AWON TO BA N SO ITAN NAA FUN WO IGBO LO NI, IYEN LO SII FAA TAWON MIIRAN SE N SO PE ATI AFONJA ATI ALIMI NI WON JO DA ILORIN SILE,IYEN NAA KIISE ODODO. 

ILORIN TI WA TIPETIPE KI ALIMI TOO DE SILUU NAA, NITORI OUN KII SE OMO ILU ILORIN. SUGBON NI TI AFONJA,ORI LOUN FI RIN DE ILU NAA KIISE ESE, OMO ILU ILORIN NI AFONJA N SE 

. SE E RI I,GBOGBO OHUN TO N SELE LAYE NI PE, IPO YOOWU TI A BA WA,KA FI SUURU SEE O, NITORI ONI KO, NITORI OLA NI BI E BA RI ENIKAN TO BA N SO PE BABA OUN KO DAA,BABA OUN KO SEEYAN, TO BA SO BABA ONI BABA DI BABA RE ,IRU OMO BEE YOO TA ILE BABA RE FUN ARAATA NI. EBI MI KO SE NI, AWON ENIYAN MI KO SEEYAN, A KO LE FIWE ALAROO LASAN, BO BA SE PE AFONJA KO SE AWON ASISE TOSE NI KOSI ENIKENI TI  IBA MAA WAA JIYAB, TABI MAA BEERE LONI-IN PE SE YORUBA LONI ILORIN NI ABI FULANI,LATI IBO SIBO.SUGBON AFONJA FI ARA ILE RE SILE, O BA ARA ITA SE ORE, LATOJO NAA LO SI TI DA OJU ITAN YORUBA RU PATAPATA

AFONJA TI LE LOMO OGOTA ODUN NIGBATI WON BA A JAGUN, TI WON SI SEGUN RE LODUN 1824, BEE TA NI  AFONJA KO GBE ILU MIIRAN TO JU ILORIN LO, TA NI YOO  WAA MAA SO ITAN PE AFONJA ATI ALIMI JO DA ILORIN SILE NI, KO RI BEE. BEE NAA LARIYANJIYAN WA NINU ORO AWON TI WON N SOPE ILU NAA N JE ILORIN NITORI PE IBI KAN WA TI WON TI N LO IRIN LAGBEGBE BAA,OKUTA YII LAWON EEYAN MAA N LO IRIN LORI RE,EYI LO SI FA A TI WON FI N PE ILU NAA NI ILORIN. OHUN TAWON TI WON N JIYAN ORO YII N SO NIPE ASIKO ODUN 1700,IRIN MELOO LO WAA WA NILUU TAWON EEYAN N RO,ADA MELOO NI WON N PON IBITI WON SI N WI YII KO KUKU BO SAARIN ONA , KA LE SOPE GBOGBO ENI TO BA N LO LO N PON ADA WON NIBE. IYEN LAWON ENIYAN KAN  SE BA WON JIYAN  TI WON SI N SOPE KIISE BEE, O SE E SE KOJE ORUKO ENITI O KOKO DA ILU NAA SILE NI WON YI PADA TO DI ILORIN . SUGBON, TA LO DA ILORIN YII SILE GAN-AN???BAYII NI ITAN NAA SE JE, E JE KA LO APAKEJI ITAN ILU ILORIN AFONJA ENUDUNJURO EYIN ENIYAN MI MO SO YI MO DURO NAA MO NBO LAIPE LORI APAKEJI ABEERE NIMI IRORUN NI MA MO LO IRORUN NI MA MO PADA MIO NI DI ESO TOLO INU IGI TIKOLE PADA WALE ASE IBA OLĂ“HUN IBA EYIN AGBA E KU OJU LO NAA OOOOOOOOO

[8:10PM, 12/4/2016] Tolohunlase: EYI NI ITAN ISEDALE ILU ILORIN APAKEJI

 Bi mo se nso lo ni APAKINNI tani o da ilu Ilorin sile e ma bami Kalo

 Bii odun 1675, okunrin kan wa TI I maa n sode kiri, oladerin loruko re. Baba oun Paapaa, ode ni won pe e, ode aperin ni, sugbon o TI jawo ode sise, nitori o ti di olori okunrin.

 Agbegbe Oyo lawon eeyan naa tedo SI, ko too di pe oladerin fun rare dagba, to SI n da se ode tire kaakiri. Oladerin lo sode sode tode agbegbe TI won maa n pe ni Ilorin loni-in yii, to SI wa ibi kan Tedo SI nibe, to se pe bo BA se ode re lo, ibe ni yoo pada si, boba lo boba ibe ni won o TI ba a. NIGBA to n pada lo si oyo, awon aburo tire naa to sepe won feran ode sise yii naa tun baa wa, bee naa lo SI di pe ilu naa n di aba, to nkun, tawon arinrin AJO a si maa tese duro nibe, nitoripe gbogbo awon ero ti won ba fee ti igbomina ati Epo de Oyo, ona tiwon yoo gba niyi, tawon miiran a si maa duro ojo meji,meta sinmi ni ibe, ki won too tun maa lo. Ko pe rara ti ilu naa fikun, tiwon si ni awon ti won n gbe nibe. Sugbon ko too di pee sele lawon ero tiwon n lo, TI won nbo yii TI fun ibe naa loruko, TI won SI maa pee  ni ile tabi ilu oladerin. Eyi lo faa tawon kan fi n so pe ile tabi ilu oladerin yii lo yipada di oruko ilu naa loni-in. Sugbon, eyi ko see fese re mule, boya ilu oladerin ni tabi ilu TI a TI nlo irin ni. Ohun kan to SAA daju, TI ko ni ARIYANJIYAN kankan ninu ni pe eni TI o da ilu naa sile, Oladerin lo n je.

Oladerin yii pe laye,ko sa Ku ni omode o dagba dada, nitoripe NIGBATI yoo fi jade layin,okan ninu awon OMO re TI di akoni, oun naa losi mu ile ati ona baba re duel, pasin loruko oun, ni bii odun 1730 ni won bii. Pasin yii naa kii se eniyan kekere, ode loun naa,sugbon oun mu ise Ogun jija mo tire, koda ise Ogun jija re ju ise ode lo, ko si SI eniti ko mo pasin yii ni gbogbo adugbo naa,oun ni won a SI maa sa BA bi oro Ogun BA feju Nitoripe AGBARA pasin PO, TI Basorun Gaa ko SI fe ki alagbara kankan wa to ju TI oun lo lagbegbe Oyo nigba naa, Gaa ni ki won loo mu pasin wa fun oun.Pasin gbo oro yii, o SI sa lo SI ola, sugbon Gaa ran awon omo Ogun re SI I, won SI wa pasin ri, won pa a sibi TI won TI BA a.

Pasin naa TI bimo to dagba daadaa ki iku re too de,Alagbin loruko oun naa,jagunjagun sini .NIGBATI kalanfo Oyabi SI n loo kogun ja Basorun Gaa,alagbin TI Gaa pa baba re wa ninu awon TI won jolo lati ilu Ilorin. Ni gbogbo asiko yii paapaa, OMO TI alagbin fun rare bi TI won n pe ni AFONJA alaya-loko(Eni TI o ni aya ,to si ni oko ti won fi n jagun)naa TI kuro lomode a-gbe-korun-losoko, jagunjagun to ni aya,to SI gbona loju Ogun ni, oun naa sitiwa ninu awon jagunjagun Aare.Agbara NLA nbe lowo AFONJA, bee ni oogun re po gan-an. Obinrin kan TI won bi sinu aafin Oyo, to SI dagba sinu aafin nibe lo bi AFONJA fun alagbin, iyen naa ni won se npe e ni omooba,iyen naa lawon rii pe Iran kerin ni AFONJA yii paapaa Nile Ilorin, bo tile je pe awon baba-baba re ni won daa sile,atipe Iran won naa lo SI TI n se olori ilu naa wa lati OJO TI won TI tee di. Sugbon bi won BA n so pe Ilorin-AFONJA, loni-in yii,ko sohun meji TI won fi nso bee jupe , ninu gbogbo awon baba re ko si eni to so ilu naa di naa bii oun ni.Nigbati agbara Afonja de oju koko,gbogbo ilu to wa lagbegbe naa lo BA jagun to SI ko won wa Ilorin, Tabi to fi won sabe Ilorin. Awon ilu bii: Kanla, Oke-suna, Ganmo, Elerinjare, Idofian,Oke-oyi, Ibare, Igbon, iresa atawon ilu miiran bee ni won da wa tele, AFONJA lo ko won sabe Ilorin; ko si soruko meji ti won n pe ilu naa nigba naa ju Ilorin ilu AFONJA lo. NIGBATI Aare ona-kakanfo oyabi yoo fi ky,AGBARA AFONJA ko legbe ni gbogbo lagbegbe Oyo ko SI SI eni kan to le duro niwaju re ko sope oun loun yio je Aare. Sugbon lodun1789, NIGBATI Aole Aro gangan je Alaafin leyin iku abiodun ,Alaafin tuntun naa ko fee fi I je Aare. Bee AFONJA TI ranse pe oye toun fee je niyen o, nitoripe ko tun si oye miiran to toun fee je.Bo tile je pe Aole nso fun awon eniyan pe oun kole GBE oye naa fun un,nitoripe omooba ni,omooba kosi leje iru oye kekere bee yen,sibe awon tiwon wa nitosi oba mo pe kiise bee yen loro naa series, won mope Alaafin kofe ki AFONJA je oye naa,nitoripe o le ma gboro soun lenu ni, NIGBATI wahala naa PO SAA o,ati kawon araalu ma mo pe iru nnkan bee yen n sele, Alaafin Aole fowo siipe ki AFONJA di Aare ona-kakanfo ile Yoruba PATAPATA hmmm e Ku ati Aaro payini itan ILORIN apakeji se bari pawo ni AFONJA se lo IPO re iPade di inu apaketa oluwa OLĂ“HUN aseda modupe lowo re fun okun ati AGBARA pelu ogbon ooye TI o funmi lati le ma ko itan bi awa OMO Yoruba se tan de ilu kookan iba eyin agba e je o ma rorun fun mi ooooo emi ni eyi wu aawi tolohunlase OMO Oodua baba owe ati akanlo ede. Owe ASA ise ati gbogbo OMO Oodua koni parun lailai ase eledumare e Ku oju lo naa

[2:04AM, 12/16/2016] Tolohunlase: ITAN ILORIN APAKETA

EKU OJO MOJI META OMO OODUA EDE O DUNBI NITORIPE BI EDE O BA DUN BI IGBE NI ILU YIO RI E SI KU ASIKOYI OLOHUN YIO RANSE AANU RE SIWA OO

[2:43AM, 12/16/2016] Tolohunlase: TI E BA GBAGBE NI APAKEJI ITAN YI ASO PE AFONJA DI AARE ONA-KAKANFO LEYIN OPOLOPO WAHALA PELU ALAAFIN AOLE PADA FARAMO NITORI TIPATIPA NI OBI FI MA UN FERAN SANGO NI ILU OYO TI ALAAFIN TUNTUN BAJE WON YIO BEERE LOWO RE PE TANI OTA RE WON YIO SI LO KO OGUN JA WON TIWON YIO SI PAWON RUN PATAPATA. EYI NI AWON ARA ILU YIO FI MO PE OBA TUNTUN TIJE NI OYO .SUGBON NIGBATI WON BEERE LOWO ALAAFIN EYI PE TANI OTA OBA ALAAFIN AOLE DA WON LOHUN PE, OTA MI LAGBARA JU MILO!AWON EEYAN KOMO OHUN TON WI O NIGBATI WON SI NYOO LENY, O NI KI WON LOSI APOMU, KIWON BA OUN KO WON NIBE, BOBA SE PE WON N WA OGUN TI WON FEE JA N. SUGBON LEYIN TI WON JAGUN NAA DE ,AWON IJOYE NLA WONYI TUN BEERE ,TAA NI OTA OBA SEE!??NIGBA NAA LO SALAYE PE AFONJA NI

AWON OLUDAMORAN OBA YII SOFUNPE IYEN KO LE BOBA SEPE AFOJA NI, KO SOHUN TI YOO SE FUN UN JU KO SIGUN LO, KO SI RAN LO SOJU OGUN TOUN NAA TI MOPE KOLE SEGUN RE BOBA TI RAN LO SOJU OGUN BEE TIKO SILE SEGUN NAA, YIO PA ARA RE TOBA PENI NITORI KOSI KAKANFO KAN TI ALAAFIN RAN LO SOGUN TI YOO TUN GBAYE LEYIN TIKOBA SEGUN,WON MAA NPA ARA WON NI.SUGBON AWON IJOYE KAN NAA WA NIBE TIWON TI N BA ALAAFIN SOTA ABENU,WON N BAA JA, WON KOKAN SOFUN  NI,BASORUN ATI OOTA NI.AWON WONYI GBO ETE NAA,WONSI  MO BORO NAA SEDE ETI AFONJA, WON SO OUN TI AOLE FEE  SE FUN LOOOTO LOOTO, KOPE TI AWON ONISE FIDE LATI OYO PE ALAAFIN RANSE OGUN TI OUN FE KI AFONJA LO.

FUN ENITI KOBA YE, ATAWON TI WON NSO ITAN PE AFONJA SAWA SI ILORIN,NITORI KI ALAAFIN MAA PAA LOYOO NI.LATI IBERE PEPE,AARE ONA-KAKANFO KAN KII BA ALAAFIN GBE NILUU OYO, EEWO NI. ALAAFIN NIKAN NII WA LOYOO, AARE YIO SI WA NILUU TIRE,TABI KOWA LEYIN ODI KAN, NIBE NI YIO MA GBE,TI YIO SI MA DA ASE TIRE PA.OHUN TO FAA NAA NIYI TOJE PE NIGBATI ALAAFIN AOLE RANSE PE KIO  MURA OGUN TI YA,ILORIN NI WON TI LOO BAA,SUGBON BI WON TI JISE FUN AFONJA MOPE OTE NI GEGE BI OUN TI BASORUN WA SOFUN,O SI MURA LATI GBA ARA RE SILE LOWO IKY AOLE ALAAFIN.

[3:13AM, 12/16/2016] Tolohunlase: ISE IKU TI OBA RAN SI AARE ONA-KAKANFO NIPE KO LOO KOLU ILU KAN TI WON N PE NI GBEJI, SUGBON WON KAN FEE FELEYI BO AFONJA LOJU NI O.ILU TI WON FEE MU LO GAN NI IWERE, WON O KAN SOFUN NI ILU IWERE YII, GBOGBO JAGUNJAGUN NI O MOPE KIISE E JA LOGUN, WON KO LE KOO, NITORI BI OLOHUN TIDA ILU NAA YATO,OKUTA LOYII KA,O SI SORO LATI TA OFA NIBE, IYEN LO SI JE KO RORUN FUN AWON TI WON WA NI ILU NAA LATI SEGUN ENIKENI TI WON BA DOJUKO. YATO SI IYEN PAAPAA NITORI PE OKE ATI APATA LOYI ILU NAA KAA BEE OHUN TAWON EEYAN IGBA NAA GBAGBO NIPE OLOHUN FUN RARE NI  KOFE KI OGUN JA ILU NAA. IDI NIYEN TO FIFI OKUTA NLA YI KA, NITOE BEE NI KOSE SI JAGUNJAGUN KAN TIIDE IWEEE KODA,KOSI ALAAFIN KAN TO SIGUN LOBE RI AFI AOLE YI TOUN NAA SITI MURA OHUN TI YOO SE SILE,KO WI KINNI KAN, O NI ISE NAA TIDI SISE NIYEN. BI OGUN BAWA BAYI,NIGBATI AARE BAKO AWON JAGUNJAGUN TIRE,ALAAFIN YOO FI AWON JAGUNJAGUN TIRE RANSE SI,BASORUN NI YOO SI SE OLORI AWON JAGUNJAGUN NAA.BAYI NI AFONJA KO AWON OMO OGUN TIRE,TO SIMU ONIKOYI NAA DANI TI BASORE NAA KO AWON OMO OGUN ALAAFIN OU. PELU OOTA,WON NI OGUN TI YA. NINU AWON OGUN OBA ABURO OBA PELU ERU RE KAN WA NI INY WON WON SI KI LO PE KI WON MA SO IBITI WON MU LO A FI TI WON BA DE IBE NIGBATI TI WON DE ODI ILU IWERE WON TOKA PE ILU TI OBA NI KI O WA JA LOGUN NIYI AFONJA NI TI KI BA SE PE IKU NI ALAAFIN N WA FUN OUN KONI PE KI OUN WA JA ILU YI LOGUN ATI PE SE KO MO PE ILU IYA ALAAFIN AJAGBO NI ILU YI NI ATI PE SE KOSI APONLE FUN ALAAFIN MO NI LE YIN EYI AFONJA NI OGUN YA..EYIN ENIYAN MI IBI NI APAKETA PARI SI SE AFONJA PADA JAGUN YI SE O SEGUN ABI KO SEGUN IPADE DI APAKERIN APAKERIN ITAN ISEDALE ILORIN EMI ONI KU AITOJO BEENI AISAN ATI WAHALA KONI KO AIROJU BAMI ATI GBOGBO EYIN OLOLUFEMI NI ASE ELEDUMARE ASA EDE ISE ATI OMO ODUDUWA.      EYI NI ITAN ILORIN APAKERIN

 BI AFONJA SE SO PE BI A BA DE IBI ISE SISE NI A MA UN SE PE OGUN YA .SUGBON NI IYALENU KAKA KI AWON OMO OGUN OBA JAGUN WO IWERE AWON OMO OGUN OBA NI WON KOJU OGUN SI TI WON SI N PAWON TI BASORUN ATI OOTA KO SI DASI IJA NAA OKAN NINU AWON OMO OGUN AFONJA ORUKO RE UNJE OPELE OUN LOFI AGADA RE PA ABURO OBA ARIN WON ATI IGBA NAA NI WON TI UN PE NI ARI AGADA PA ABURO OBA NIGBATI WON SE EYI TAN WON KO TETE PADA SILE NI ALAAFIN AOLE RANSE SI WON PE SO KOSI TI WON KO FI WALE NI BASORUN ATI OOTA RANSE PADA PE AWON OMO OGUN OBA RI AWON FI AWON SI TI DA SERIA FUN WON NIGBATI WON DE ODO OBA OBA TUN RAN WON PADA PE KI WON SA WA JE ISE TI OUN RAN WON SUGBON WON KO DA LOHUN JU PE WON RANSE SI PE ENU RE KO TO SI ORO MO PE KIO LO SI IGBAWO KO PA ARA RE ALAAFIN AOLE NAA TIUN FURA PE IKU OUN LOKU TI WON UN WA BI WON SE JE ISE FUN O SI BA AWON OMO RE SORO PELU OUN TIWON YIO SE LEYIN EYI NI O BA MU OOFA META PELU IGBA FUNFUN KAN NI O BA TA OFA IKAN SI ARI WA IKAEJI SI ILA OORUN IKETA SI GOOSU NI O BA SO PE BI EYIN OMO YORUBA KO SE GBORO SI OUN LENU LATI ONI LO ENU YIN KO TUN KO MO

KOTUN SI ISOKAN NI ARIN YIN MO GBOGBO IBITI OUN TA OFA SI GBOGBO IBE NI WON YIO TI MA MU YIN NI ERU O SI FO IGBA FUNFUN NAA MOLE LEYIN NAA O SI FI ADE DE IGBA FUNFUN TO FO NAA PE ASE GUN EPE NAA IGBA ISOKAN YORU  NI AIPE WON FI OBA MIIRAN JE NI ILU OYO .SUGBON NIGBATI AFONJA ATI AWON YO KU GBO PE WON TI FI OBA MIIRAN JE NI OYO NI AFONJA BA KEDE PE ILORIN KOSI NI ABE OYO MO OOO BAKAN NAA NI OPELE BAALE GBONMU NAA KEDE PE OUN NAA KO SI NI ABE OYO MO KOSI SI ALAGBARA KAN TIO LE KOJU AFONJA PELU OPELE NI IGBA NAA IBI YI NI ITAN ILORIN APAKERIN PARI SI IPADE DI APAKETA KINI O WA SE LE LEYIN TI AFONJA TI YO ILORIN KURO LABE OYO MO SO YI MODURO NAA ASOJU ORO LOPA ELENPE AKOKO EMI ONI SI WI BEENI EYIN KONI SIMI GBO IKU KONI PAWA NI AIPE OJO OSI ARUN KONI SIWA NI IPO PADA EDE ASA ISE PELU EDE YORUBA KONI PARUN LAILAI ASE NITI ELEDUMARE E KU OJU LONAA OOOOOOOOOO IBA OLOHUN IBA EYIN AGBA EYONU SIMI OOOOOOOOO

ERE OKANJUA

  ITAN IJAPA OBO ATI EWORO

 OBO ATI EWORO NI WON JO JE ORE KORIKOSUN  ORE TIMOTIMO NIWON NI OJO KAN WON LO BA ERIN SE ISE TI O SI FUN WON NI EBUN BUREDI NILA KAN PE KIWON PIN NI WON BA DE ILE NI EWORO NI OUN NI OUN YIO PIN OBO NI RARA OUN NI OUN YIO PIN NI ORO YI WA DI IJA LAARIN WON NI NI WON BA KO EJO LOSI ODO IJAPA PE KIO BA AWON PIN NI IJAPA NI OUN YIO GBA OWO OYA TIO BA SE ISE TI WON BE OUN FUN NI O BA PIN SUGBON OPIN IKAN JU IKAN LO NI O BA BU LARA EYI TO TOBI SUGBON NI IGBATI O BU TAN OTUN KERE JU IKEJI LO O TUN BU IKEJI NAA JE LEYIN NAA OTUN KERE JU TI AKOKO LO OTUN BU JU EKEJI LO OTUN TUN BU TITI TIO FI SEKU DIE NIO BA SOPE EYI TOKU NI OUN YIO FI SE OWO YA OUN NI O BA SO OUN NAA SI ENI NI KOBA SI NKANKAN MO FUN OBO ATI EWORO  NI WON BA SE ABA MO OPOLOPO AWON EDA NI WON TI FI OWO BOLE NITORI OKANJUA ATI AINI ITELORUN E SORA OOOO EMI OMO YIN EYIWU AAWI TOLOHUNLASE OLA ANOBI ORO GBOGBO WA KONI JASI IFOWOBOLE AMIN ASE ELEDUMARE

CATEGORIES
TAGS
Share This

COMMENTS

Disqus ( )