​ORIKI ILU IWO

ORIKI ILU IWO
………………………………………………………..

IWO OLODO OBA

OMO ATENI OLA LEGELEGE FORI SAGBEJE OMI

IWO OLODO OBA NILE ODIDERE

IWO TIKO NI ILEKUN

IWO TIKO NI KOKORO

ERU WEWE NIWON NFI NDELE BABA TOBI WON LOMO

IWO OMO ATENI SOLA 

IWO OMO ATENI GBORE

EYIN LOMO KURUKURU AJABO

EYIN LOMO ELEWU IGBAGO

OMO ENIKAN LA JU ENIKAN LO

IWO OMO ODO OBA

NILE OMO OBA TODU MERIN

ANIBI ARA IWO KOLA 

ANIBI ARA IWO KO LOWO LOWO

EYITI E DE MORO TO BEERE 

NILE OBA TODU MERIN 

IWO LOMO AGBOBI SORO

IWO LOMO EGUNGUN SOKOTI

EGUNGUN OBA IWO OLODO OBA NI

IWO NI ODIDERE PE TENU RE TE KOROYI

IWO JIYAN JIYAN

IWO O JIYAN KANKAN NILE BABA TOBI YIN

ISE MEJI LAMO IWO MO

IWO TIKO BA TERAN

YIO SOLOOLA

EYIN LOMO OLOOLA TI NSA KEKE

EYIN LOMO OLOOLA TI NBABAJA

EYIN LOMO OLOOLA TI NWA EKO IDE MU 

ODIDERE KOJE KAMO IBI IWO GBALO

IRU OKERE KOJE KI OMI OBA O TORO

BOMI OBA KOBA TORO

KILAFE MU BO OBA MU BOSUN

KILAFE MU BO JAGUN TERE ETI IYE METU 

NILE IWO OMO ODO OBA

CATEGORIES
TAGS
Share This