​IDANILEKO NIPA ORI BIBO NI ILE YORUBA

Ori lonise, eda eni lalayanmo,Ori mi asingbara

ileke, ada ni wale aye ,mase gbagbe mi, Mose

bori leja fi n la bu,Ori laponran fi n laagba

iroko, Ori mi ma a pada leyin mi, gbe mi debi

ire,Bori ba n seelomii , won a leegun ni,

Beleda ba n seelomii, won a si loosa ni, Orisa

bi ori o si, ori eni la ba kobi bo.Ori bibo ni ile

Yoruba je ona pataki ti a fi n ba eleda eni

soro ati be ori eni. Orisa pataki kan ni a mo

Ori si laarin awon ookanlenigba irunmole.Ko si

se fowo roti seyin rara. Itan kan so ninu ese

Ifa kan wipe eye ki i fo, ko gbagbe ori e sile ,bi

eja ji ninu ibu, tohun tori e lo jo n ji,bi erin ba

ji nigbo, tohun tori e lo jo n ji, bi efon ba ji

lodan, tohun tori e lo jo n ji,A ki i nikan sun ka

a nikan ji,ba a ba nikan sun,Olorun oba ni ji ni

loju orun.
A difa fun awon meta ti won jo sun, akuko

adiye ji eni kinni,ohun ba jawon mejeeji

yoku,awon meji wa n beere lowo e wipe, bawo

lo se ji?O ni Olorun oba lo jihun loju orun.

Awon igba irunmole n binu Ori, won binu Ori

tititi,won o pada leyin Ori, Ori ba binu si won

o da gbogbo won lagara.O mu Sango wole ni

Koso, O mu Oya wole nile Ira, O mu Ogun wole

ni Ire ati bee bee lo.Bi ori bibo ba yo si

eniyan,Odu Ifa Odi meji ni yo jade loju opon

Ifa babalawo.Won le ni ki o fi eja aro tabi eye

etu pelu omi, obi abata oloju merin, oti

sinaapu ati owo boo.Ale ni won ma a n bo ori

fun eniyan. Leyin eyi, oro eniti won bori fun ti

dayo, ki ona la fun ki o si ma rise, ko ma

gbadun loku.

ORIKI ORI:

Ori Onise

Apere

Atete gbeni ju Orisa

Ori atete niran

Ori lokun

Ori nide

Ko si Orisa ti dani gbe leyin Ori eni

Ori ni seni ta a fi dade owo

Ori ni seni ta a fi tepa ileke woja

Ori ni seni ta a fi lo mosaaji aso oba

Ori gbe mi

Ori la mi

Ori ma pada leyin mi Ori mi gbemi debi giga.

Mo se Amin….Ase…koribe funmi.

Awon Orisirisi Odu Ifa/Apola Odu Ifa tosoro

nipa Pataki Orisa ti Ori je.

Lara won ni….

odu Irete Ofun

Atefun-tefun

Dia fun Okanlenirino Irunmole

Won nlo sode Apere

Atefun-tefun eyin oni

Awo Ori lo dia fun Ori

Ori nlo sode Apere

Won ni ki won sakaale ebo ni sise

Ori nikanikan ni nbe leyin ti nsebo

Ebo Ori waa da ladaju

Nje Ori gbona ju Orisa

Ori ma gbona ju orisa

Ori nikan-nikan lo ko won l’Apeere

Ko si Orisa to to nii gbe

Leyin Ori eni

……………………….
Ogunda Oworin:

Okun kun nore nore

Osa kun lengbe-lengbe

Olowa nrowa

Alasan nran Asan

Agba imole wo ehun oro, o ri pe ko sunwon

O gi irunmu d’imu yayaya

O gi irungbon di aya pen-pen-pen

D’ifa fun isheshe merin

Ti won nse olori oro n’Ife

“Nje, kinni a baa bo ni Ifa?”

Isheshe ni a ba bo, ki a to bo Orisa

Baba eni ni isheshe eni

Iya eni ni isheshe eni

Ori eni ni isheshe eni

Ikin eni ni isheshe eni

Odumare ni Isheshe

Isheshe, mo juba ki nto s’ebo.

Adarafunwa

CATEGORIES
TAGS
Share This