​¤BALOGUN IBIKUNLE¤

¤BALOGUN IBIKUNLE¤

Ni Ilu Ijado leti Ogbomoso ni a ti bi Ibikunle ki

o too lo si Ibadan. Bi o tile je pe o ti nlowo

ninu ogun orisirisi ti Ibadan nja, ni aye Baale

Olugbode ni o je Balogun, lowo, o loogun, o si

ni oko(farm) lopolopo. Bee si ni o kole nla, o

si fa agbala repete, eyi lo je ki woo maa ki i

pe:

A r’owo lo geregere nile olomi

O loko lOgbere.

Ibikunle loko lOdo-Ona

A boju oko gberengbere

To fi dodi Adesegun.

Alagbala jayajaya baba Kuejo

Alagbala ‘Bikunle joko elomiran lo.

A bagbala to koriko sare tan.

A gbo pe gbogbo ogun to lo lo fere se tan.

Iwadi tun fi ye wa pe opelope re ni o jeki ara

Ibadan segun lasiko ogun Ijaye. O se

gudugudu meje ati yaaya mefa lasiko ogun

naa. Bakan naa ni Olorun fun un ni ebun omo

pupo. Orisirisi iwa akin lo hu nigba aye re.

Ni asiko kan o fe lo jagun Ara, yoo si gba Ede

koja. Timi ni ki o ma se gba aarin ilu oun koja

bi ko ba fe wahala, ko si jiyan sugbon o do ti

ilu naa. Awon omo ogun re si nkore nnkan oko

won diedie. Awon ara Ede to jade ko le wole;

awon to wole ko le jade. Nigba ti inira mu

awon ara ilu, opolopo ebun ni Timi fi bebe fun

idariji.

Ona ero ni akinkanju ologun naa gba ku. Leyin

ogun Ijaye a gbo pe Ibikunle fe fi aja bo Ogun.

Nibi ti omo eyin re kan t4 fe be aja naa, ada

bo lowo re, ada naa ba Ibikunle ni itan, ogbe

(wound) naa si po gidigidi, ogbe naa ni o si

gbe lo si oju ogun Kutuje ti wn ba awon Egba

ja. Sugbon awon ara Ibadan padanu eniyan

pupo ninu ogun naa. Olorun lo sa fi Alaafin

Adelu se sababi ti o pari ija naa fun won.

Awon to si lo si ogun ko dari dele ba Baale

Olugbode laye mo, o ti ku. Bi Ibikunle naa si ti

ti ogun naa de lo ku. Ki i se pe oju ogun lo ti

pade ohun to pa a yii sugbon ogbe to ti gba

lasiko ti o nbo Ogun lo pa a.

Awon agba so pe oun lo dabi Balogun to

lokiki to si tun lagbara julo ninu itan Ibadan.

Yooba Dun!

Oyin Ni!

CATEGORIES
TAGS
Share This